25 Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ; àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ.
26 Ará, ẹ kíyèsí ohun tí nígbà tí a pè yín. Bí ó ti ṣe pé, kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn nípa ti ara, kí í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà, kì ì ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́lá ni a pè.
27 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára.
28 Ó ti yan ètò tí ayé kẹ́gàn, tí wọn kò kà sí rárá, láti sọ nǹkan tí wọ́n kà sí ńlá di ohun asán àti aláìwúlò.
29 Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀.
30 Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kírísítì Jésù ẹni ti ó já sí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyi ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa.
31 Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”