4 Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kírísítì Jésù.
5 Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo.
6 Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kírísítì ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín.
7 Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyì ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kírísítì.
8 Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì.
9 Ọlọ́run, nípaṣẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa, jẹ́ Olótítọ́.
10 Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì, pé kí gbogbo yín fohùnsọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyàpá láàrin yín, àtipé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà.