6 Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kírísítì ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín.
7 Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyì ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kírísítì.
8 Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì.
9 Ọlọ́run, nípaṣẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa, jẹ́ Olótítọ́.
10 Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì, pé kí gbogbo yín fohùnsọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyàpá láàrin yín, àtipé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà.
11 Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kiloe sọ di mímọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrin yín.
12 Ohun tí mo ń sọ ni pé: Olúkúlùku yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Pọ́ọ̀lù”; “Èmi tẹ̀lé Àpólò”; òm̀íràn, “Èmi tẹ̀lé Kéfà, ìtúmọ̀, Pétérù”; àti ẹlòmìíràn, “Èmi tẹ̀lé Kírísítì.”