1 Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arakùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú ihà. Ọlọ́run samọ̀nà wọn nípa rírán ìkùúkù ṣíwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi òkun pupa já.
2 A lè pe eléyìí ní ìtèbọmi sí Mósè nínú ìkùúkù àti nínú omi òkun.
3 Nípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà.
4 Wọ́n mu nínú omi tí Kírísítì fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kírísítì. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú ihà náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára.
5 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ lẹ́yin èyí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò ṣe ìgbọ́ràn sí Ọlọ́run. Òun sì pa wọ́n run nínú ihà.