22 Kí ni ẹ̀ ń gbìyànjú láti ṣe? Àwa ha ń mú Olúwa jowú bí? Àwa ha ní agbára jù ú lọ?
23 “Ohun gbogbo ni o yẹ fún mi,” ṣùgbọ̀n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè. “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ń gbe ni rò.
24 Má ṣe ronú nípa ara rẹ̀ nǹkan; ṣùgbọ́n kí olúkúkù máa wá ire ọmọnikéji rẹ̀.
25 Jẹ ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá ń tà lọ́jà. Má ṣe gbìyànjú láti wádìí lọ́wọ́ ẹni tí ń tà á nítorí ẹ̀rí ọkàn.
26 Nítorí “Ayé àti gbogbo nǹkan rere tí ń bẹ nínú rẹ̀, tí Olúwa ni wọ́n jẹ́.”
27 Bí ẹnìkẹ̀ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àṣè láti jẹun, bá a lọ. Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rún. Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àṣè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn.
28 Bí ẹnikẹ́nì bá sì kìlọ̀ fún un yín pé a ti fi ẹran yìí rúbọ sí òriṣà, má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹ̀rí ọkàn tí ó kìlọ̀ fún ọ́ pé a ti fi rúbọ sí òrìṣà.