25 Jẹ ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá ń tà lọ́jà. Má ṣe gbìyànjú láti wádìí lọ́wọ́ ẹni tí ń tà á nítorí ẹ̀rí ọkàn.
26 Nítorí “Ayé àti gbogbo nǹkan rere tí ń bẹ nínú rẹ̀, tí Olúwa ni wọ́n jẹ́.”
27 Bí ẹnìkẹ̀ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àṣè láti jẹun, bá a lọ. Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rún. Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àṣè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn.
28 Bí ẹnikẹ́nì bá sì kìlọ̀ fún un yín pé a ti fi ẹran yìí rúbọ sí òriṣà, má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹ̀rí ọkàn tí ó kìlọ̀ fún ọ́ pé a ti fi rúbọ sí òrìṣà.
29 Nǹkan tí ó ṣe pàtàkì ní irú ipò yìí ni ẹ̀rí ọkàn àti èrò ọkùnrin náà, nítorí kì í ṣe ẹ̀rí ọkàn ẹlòmìíràn ní a ó fi dá òmìnira mi lẹ́jọ́.
30 Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, è é ṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búbúrú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún.
31 Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkohun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run.