8 Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbérè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan.
9 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n.
10 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.
11 Gbogbo àwọn nǹkan tí mo ń wí wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n sì jẹ́ àpẹrẹ, fún wa, wọ́n kọ wọ́n sílẹ̀ bí ikìlọ̀ fún wa láti yàgò kúrò nínú síṣe àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. A kọ èyí sílẹ̀ fún kíkà wa ní àkókò yìí tí aye fi ń lọ sópin.
12 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à subú.
13 Kò sí ìdànwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó ti bá ènìyàn rí, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlórun, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ̀n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ́yin baà lè faradà á.
14 Nítorí náà, ẹ̀yín olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.