11 Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òùngbẹ, a wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan.
12 Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i.
13 Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsinyìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.
14 Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́.
15 Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbààrún olùkọ́ni nínú Kírísítì, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kírísítì Jésù ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìyìn rere.
16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi.
17 Nítorí náà ni mo ṣe rán Tìmótíù sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo.