10 Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọn ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀: àgbérè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn.
11 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń wí nínú ìwé sí i yín pé, ẹ kò gbọdọ̀ darapọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó bá pe ara rẹ̀ ni arákùnrin, ṣùgbọ́n tí ó fi ẹ̀ṣẹ̀ àgbérè tàbí wọ̀bìà, ìbọ̀rìṣà àti ẹlẹ́gàn tàbí ìmutípara àti alọ́nilọ́wọ́gbà. Ẹ má ṣe bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ oúnjẹ pọ̀ rárá.
12 Kì í ṣe iṣẹ́ mi láti máa ṣe ìdájọ́ (àwọn aláìgbàgbọ́) àwọn tí wọn kò sí nínú ìjọ. Dájúdájú iṣẹ́ tiwa ni láti ṣe ìdájọ́ àti láti fi ọwọ́ líle mú àwọn tí ń bẹ nínú ìjọ.
13 Ọlọ́run nìkan ni onídájọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. “Ẹ lé àwọn ènìyàn búburú náà kúrò láàrin yín.”