3 Lóòtọ́ èmi kò sí láàrin yín, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí àti pé, ní orúkọ Olúwa Jésù Kírísítì, mo tí ṣe ìdájọ̀ lórí irú ẹni bẹ́ẹ̀, bí ẹni pé mo wá láàrin yín.
4 Ní orúkọ Jésù Kírísítì. Nígbà tí ẹ̀yin bá péjọ, àti ẹ̀mí mi, pẹ̀lú agbára Jésù Kírísítì Olúwa wa.
5 Kí ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé sátanì lọ́wọ́ fún ìparun ara, kí ó baà le gba ẹ̀mí là ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì.
6 Ìfọ́nnú yín kò dára. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní i mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú?
7 Nítorí náà ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò nínú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ìyẹ̀fun titun, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà. Nítorí à ti fi ìrekọjá wa, àní Kírísítì ni a ti pa láti fi ṣe ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.
8 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankan àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo.
9 Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbérè ènìyàn.