4 Ní orúkọ Jésù Kírísítì. Nígbà tí ẹ̀yin bá péjọ, àti ẹ̀mí mi, pẹ̀lú agbára Jésù Kírísítì Olúwa wa.
5 Kí ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé sátanì lọ́wọ́ fún ìparun ara, kí ó baà le gba ẹ̀mí là ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì.
6 Ìfọ́nnú yín kò dára. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní i mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú?
7 Nítorí náà ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò nínú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ìyẹ̀fun titun, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà. Nítorí à ti fi ìrekọjá wa, àní Kírísítì ni a ti pa láti fi ṣe ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.
8 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankan àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo.
9 Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbérè ènìyàn.
10 Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọn ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀: àgbérè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn.