6 Ìfọ́nnú yín kò dára. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní i mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú?
7 Nítorí náà ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò nínú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ìyẹ̀fun titun, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà. Nítorí à ti fi ìrekọjá wa, àní Kírísítì ni a ti pa láti fi ṣe ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.
8 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankan àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo.
9 Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbérè ènìyàn.
10 Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọn ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀: àgbérè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn.
11 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń wí nínú ìwé sí i yín pé, ẹ kò gbọdọ̀ darapọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó bá pe ara rẹ̀ ni arákùnrin, ṣùgbọ́n tí ó fi ẹ̀ṣẹ̀ àgbérè tàbí wọ̀bìà, ìbọ̀rìṣà àti ẹlẹ́gàn tàbí ìmutípara àti alọ́nilọ́wọ́gbà. Ẹ má ṣe bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ oúnjẹ pọ̀ rárá.
12 Kì í ṣe iṣẹ́ mi láti máa ṣe ìdájọ́ (àwọn aláìgbàgbọ́) àwọn tí wọn kò sí nínú ìjọ. Dájúdájú iṣẹ́ tiwa ni láti ṣe ìdájọ́ àti láti fi ọwọ́ líle mú àwọn tí ń bẹ nínú ìjọ.