33 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn ẹrù rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn,
34 dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí ó bá wà nílé ọkọ, irú ìṣòro kan náà ni ó dojú kọ. Ọmọbìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa ṣàkìtiyan láti tẹ́ Olúwa lọ́rùn ní gbogbo ìwà àti ìṣe àti ní tí ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe àkíyèsí ohun púpọ̀, yóò máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn.
35 Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbon kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn.
36 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun kò ṣe ohun tí ó yẹ sí wúndíá rẹ̀ bí ó bá ti di obìnrin, bí ó bá sí tọ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó ṣe bí ó tí fẹ́, òun kò dẹ́sẹ̀, jẹ́ kí wọn gbé ìyàwó.
37 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó dúró sinsin ni ọkàn rẹ̀, tí kò ní àìgbọ́dọ̀ má ṣe, ṣùgbọ́n tí ó ní agbára lóri ìfẹ́ ara rẹ̀, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé, òun ó pa wúndíá ọmọbìnrin òun mọ́, yóò ṣe rere.
38 Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹni tí ó fi wúndíá ọmọbìnrin fún ni ní ìgbéyàwó, ó ṣe rere; ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi fún ni ní ìgbéyàwó ṣe rere jù lọ.
39 A fi òfin dé obìnrin níwọ̀n ìgbà tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ wà láàyè, bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn, tí ó bá wù ú ó sì gbọdọ̀ jẹ́ ti Olúwa.