23 Mo ṣe èyí láti lè rí ààyè láti wàásù ìyìn rere sí wọn àti fún ìbùkún tí èmi pàápàá ń rí gbà, nígbà tí mo bá rí i pé wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn Kírísítì.
24 Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú rẹ̀ ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò kìn-ín-ní. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ baà le borí.
25 Láti borí nínú eré ìdíje, ẹ ní láti sẹ́ ara yín nínú ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó lè fá yín sẹ́yín nínú sísa gbogbo agbára yín. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run tí kò lè bàjẹ́ láéláé.
26 Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú àmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lóju. Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà.
27 Ṣùgbọ́n èmi ń ń kó ara mi níjànu, mo sì n mú un wá sí abẹ́ ìtẹríba, pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún áwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi fún rara mi má se di ẹni ìtanú fún ẹ̀bùn náà.