2 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a ba ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo.
3 Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìranti ẹ̀ṣẹ̀ lọdọ́ọ̀dún.
4 Nítorí ko ṣeeṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.
5 Nítorí náà nígbà tí Kísítì wá sí ayé, ó wí pé,“Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ,ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi;
6 Ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ niìwọ kò ní inú dídùn sí.
7 Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsí i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọọ́ nípa ti èmi)mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ”
8 Nígbà tí o wí ni ìṣáajú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọ̀rẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin).