16 Kí o má bá à si àgbérè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Èsau, ẹni tí o titorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀.
17 Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ̀yìn náà, nígbà tí ó fẹ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri àyè ìronupìwàdà, bí o tilẹ̀ kẹ pé ó fi omijé wa a gidigidi.
18 Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì.
19 Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ si i fún wọn mọ́:
20 Nítorí pé ara wọn kò lè gba ohun tí ó palaṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni o farakan òkè náà, a o sọ ọ ni òkúta, tàbí a o gun un ní ọ̀kọ̀ pa.”
21 Ìran náà sì lẹ̀rù to bẹ́ẹ̀ tí Móṣè wí pé, “Ẹrù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.”
22 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Síónì, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerúsálémù ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn áńgẹ́lì àìníye,