23 Si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, o
24 Àti sọ́dọ̀ Jésù alárinà májẹ̀mú titun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Ábélì lọ.
25 Kíyèsí i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélomélo ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀hìndè sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá:
26 Ohùn ẹni ti o mi ayé nígbà náà: ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti ṣe ìlérí, wí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi ki yóò mi kìkì ayé nìkan, ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.”
27 Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀.
28 Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a ni oore-ọfẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́tẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀.
29 Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó nírun ni.”