8 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, njẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ.
9 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríbà fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè?
10 Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o ba ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀.
11 Gbogbo ìbáwí kò dábì ohun ayọ̀ nísinsìn yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹ́yìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.
12 Nítorí náà ẹ na ọwọ́ tí o rọ, àti èékún àìlera;
13 “Kí ẹ sì ṣe ipa-ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kuku wò ó sàn.
14 Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa: