1 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí àti wọ inú ìsinmi rẹ̀ fún wa, ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù, kí ẹnikẹ́ni nínú yín má baà dà bí ẹni pé ó tí kùnà rẹ̀.
2 Nítorí tí àwá gbọ́ ìwàásù ìyìn rere, gẹ́gẹ́ bí a ti wàásù rẹ̀ fún àwọn náà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kò ṣe wọ́n ní ire, nítorí tí kò dàpọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú àwọn tí ó gbọ́ ọ.
3 Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí,“Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpilẹ̀ ayé.
4 Nítorí ó ti sọ níbìkan ní ti ọjọ́ kéje bayìí pé, “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.”