3 Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí,“Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpilẹ̀ ayé.
4 Nítorí ó ti sọ níbìkan ní ti ọjọ́ kéje bayìí pé, “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.”
5 Àti níhìn yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.”
6 Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a tí wàásù ìyìn rere náà fún ní ìṣáajú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn:
7 Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dáfídì pé, “Lònìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí niṣáájú,“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.”
8 Nítorí, ìbá ṣe pé Jóṣúà tí fún wọn ní ìsinmi, òun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi mìíràn lẹ̀yìn náà,
9 nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.