8 Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, òun ó sì sún mọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì.
9 Ẹ banújẹ́, ẹ sọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́.
10 Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga.
11 Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́.
12 Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbà là tí ó sì le parun, Ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹni kejì rẹ lẹ́jọ́?
13 Ẹ wá nísinsìn yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.”
14 Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkuuku sáà ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ.