1 Ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere nípa Jésù Kírísítì, Ọmọ Ọlọ́run.
2 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Àìṣáyà pé:“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mí ṣíwájú rẹ,Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”
3 “Ohùn ẹnìkan tí ń kígbe ní ihà,‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,ẹ se ojú-ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”
4 Jòhánù dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní ihà, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
5 Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Jùdíà, àti gbogbo ènìyàn Jerúsálémù jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọmi ni odò Jọ́dánì, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn.