Máàkù 14 BMY

A Da Tùràrí sí Ara Jésù

1 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni Àjọ ìrékọjá àti àjọ tí wọ́n ń fi àkàrà àìwú se ku ọ̀túnla. Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jésù ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á.

2 Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “A kò ní mú un ní ọjọ́ Àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n.”

3 Nígbà tí ó sì wà ní Bẹ́tanì ni ilé Símónì adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti ìgò òróró ìpara olówó iyebíye, ó sí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jésù lórí.

4 Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò?

5 Òun ìbá tà á ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn talákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára.

6 Ṣùgbọ́n Jésù wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé? Nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi?

7 Nígbà gbogbo ni àwọn talákà wà ní àárin yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkugbà tí ẹ bá fẹ́.

8 Ó ti ṣe èyí tí ó lè ṣe, Ó ti fi òróró kùn mí ni ara ní ìmúra sílẹ̀ de ìgbà tí wọn yóò sin òkú mi.

9 Lóótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”

10 Nígbà náà ni Júdásì Ìsíkáríọtù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfàá, láti ṣètò bí yóò ti fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.

11 Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì pinnu láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

12 Ní ọjọ́ kìnínní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèṣè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àṣè ìrékọjá?”

13 Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru iṣà omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

14 Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baale náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé: Ní bo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àṣè ìrékọja pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’

15 Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèṣè sílẹ̀ dè wá.”

16 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárin ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jésù tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àṣè ìrékọjá.

17 Nígbà tí ó di alẹ́, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé ṣíbẹ̀.

18 Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jésù wí pé, “Lóòtọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fí mí hàn.”

19 Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọkọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?”

20 Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi jẹun nísinsin yìí ni.

21 Ní tòótọ́ Ọmọ-Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: Ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ-Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.”

22 Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jésù mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.”

23 Ó sì tún gbé ago wáìnì, ó gbàdúrà ọpẹ́ sí Ọlọ́run. Ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.

24 Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi ti májẹ̀mú túntún, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

25 Lóótọ̀ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní titun nínú ìjọba Ọlọ́run.”

26 Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè ólífì lọ.

Jésù Sọ Àṣọtẹ́lẹ̀ pé Pétérù Yóò Ṣẹ́ Òun

27 Jésù sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ ń bọ̀ wá kosẹ̀ lára mi ni oru òní, a ti kọ̀wé rẹ pé:“ ‘Èmi yóò lu olùsọ́-àgùntànàwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká.’

28 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, Èmi yóò ṣíwájú yin lọ sí Gálílì.”

29 Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn, ó wí pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá.”

30 Jésù wá wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tóó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ̀ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”

31 Ṣùgbọ́n Pétérù faraya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́ rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.

Ọgbà Gétísémánì

32 Nígbà tí wọ́n dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní ọgbà Gétísémánì. Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó dè mí níhìnín títí n ó fi lọ gbàdúrà.”

33 Ó sì mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi.

34 Ó sì wí fún wọn pé, “Títí dé kú. Ẹ dúró níhìnín kí ẹ sì máa mi sọ́nà.”

35 Ó sì lọ ṣíwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá.

36 Ó sì wí pé, “Á bà Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kìí ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò se èyí tí ìwọ fẹ́.”

37 Nígbà tí ó sì páda dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Pétérù pé, “Símónì, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi sọ́nà fún wákàtí kan?

38 Ẹ máa sọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ”

39 Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú.

40 Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ì bá fún un.

41 Ó sì wá nígbà kẹ́ta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́.

42 Ẹ dìde, Ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòòsí!”

A Mú Jésù

43 Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Júdásì ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ́ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbààgbà Júù ni ó rán wọn wa.

44 Júdásì tí fí àmì fún wọn wí pe, “Ẹni tí mo bá fi ẹnu kò lẹ́nu nínú wọn, òun ní Jésù, Ẹ mú un.”

45 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, Júdásì lọ sì ọ̀dọ̀ rẹ̀ tààrá, ó wí pé, “Rábì!” ó sì fi ẹnu kò Jésù lẹ́nu.

46 Wọ́n sì mú Jésù.

47 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró idà rẹ̀ yọ, ó fi sá ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ge etí rẹ̀ bọ́ sílẹ̀.

48 Nígbà náà Jésù dáhùn, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé Èmi ni ẹ̀yin jáde tọ̀ wá bi olè, ti ẹ̀yin ti idà àti kùmọ̀ láti mú?

49 Ojoojúmọ́ ni èmi wà pẹ̀lú yín ní tẹ́ḿpìlì, tí mo ń kọ́ni; ẹ kò mú mi. Ṣùgbọ́n eléyìí ṣẹlẹ̀, kí ohun tí ìwé Mímọ́ wí lè ṣẹ.”

50 Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, wọ́n sá lọ.

51 Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ bo ìhòòhò rẹ̀ àwọn ọmọ-ogun gbìyànjú láti mú òun náà.

52 Ó sì fi aṣọ funfun náà sílẹ̀ fún wọn, ó sì sá lọ ní ìhòòhò.

Jésù Níwájú Sahẹ́ńdírì

53 Wọ́n mú Jésù lọ sí ilé olórí àlùfáà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù àti àwọn olùkọ́-òfin wọn péjọ síbẹ̀.

54 Pétérù tẹ̀lé Jésù lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná.

55 Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rí èkè sí Jésù, èyí tí ó jọjú dáadáa láti lè dájọ́ ikú fún un. Ṣùgbọ́n wọn kò rí.

56 Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ̀n ní kò bá ara wọn mu

57 Níkẹyìn àwọn kan dìde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ní

58 “A gbọ́ tí ó wí pé ‘Èmi yóò wó tẹ́ḿpìlì tí ẹ fi ọwọ́ kọ́ yìí, nígbà tí yóò bá sì fi di ọjọ́ kẹta, èmi yóò kọ́ òmíràn ti a kò fi ọwọ́ ènìyàn kọ́.’ ”

59 Ṣíbẹ̀, ẹ̀rí i wọn kò dọ́gba

60 Nígbà náà ni àlùfáà àgbà dìde, ó bọ́ ṣíwájú. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi Jésù léèrè, ó ní, “Ṣé o kò ní fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn ọ? Kí ni ìwọ gan an ní sọ fúnrarẹ?”

61 Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́.Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ò ní, “Ṣé ìwọ ni Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run?”

62 Jésù wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni: Ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ-Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ-Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọ̀sánmọ̀ ojú ọ̀run.”

63 Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “Kí ló kù tì a ń wá? Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rí fún?

64 Ẹ̀yin fúnra yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?”Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ìkú.”

65 Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ̀ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń gbà a lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùsọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú.

Pétérù Sẹ́ Jésù

66 Ní àkókò yìí Pétérù wà ní ìṣàlẹ́ inú àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Nínú àgbàlá yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin àlùfáà àgbà kíyèsí í tí Pétérù ń yáná.

67 Nigba tí ó rí Pétérù tí ó ti yáná, Ó tẹjú mọ́ ọn, ó sì sọ gbangba pé,“Ìwọ pàápàá wà pẹ̀lú Jésù ara Násárẹ̀tì.”

68 Ṣùgbọ́n Pétérú ṣẹ́, ó ni, “N kò mọ Jésù náà rí; ohun tí ó ń sọ yìí kò tilẹ̀ yé mi.” Pétérù sì jáde lọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Àkùkọ sì kọ.

69 Ọmọbìnrin yẹn sì tún rí Pétérù. Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀. Ó ní, “Ọkùnrin yìí gan an jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù.”

70 Ṣùgbọ́n Pétérù tún ṣẹ́.Nígbà tí ó sí tún ṣẹ díẹ̀ sí i, àwọn tí wọ́n dúró lẹ́gbẹ́ Pétérù wá wí fún un pé, “Láìṣe àní àní, ara wọn ni ìwọ. Nítorí ará Gálílì ni ìwọ náà.”

71 Nígbà náà ni Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́ ó sì ń búra, ó ni, “N kò mọ ẹni ti ẹ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí rí!”

72 Lójú kan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Pétérù rántí ọ̀rọ̀ Jésù fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, ìwọ yóò ṣẹ́ mí nígbà mẹ́ta.” Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkùn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16