Máàkù 16 BMY

Àjíǹde

1 Nígbà tí ọjọ́ ìsinmi sì kọjá, Màríà Magidalénì àti Sálómì àti Màríà ìyá Jákọ́bù àti Sálómè mú òróro olóòórùn dídùn wá kí wọn bá à le fi kun Jésù lára.

2 Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sè, wọ́n wá sí ibi ibojì nigbà tí òòrùn bẹ̀rẹ̀ sí yọ,

3 wọn sì ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ni yóò yí òkúta náà kúrò lẹ́nu ibojì fún wa?”

4 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn sì wò ó, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta tí ó tóbi gidigidi náà kúrò.

5 Nígbà tí wọ́n sì wọ inú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́mọkùnrin kàn tí ó wọ aṣọ funfun, ó jókòó ní apá ọ̀tún, ẹnú sì yà wọn.

6 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù: Ẹ̀yin ń wá Jésì tí Násárẹ́tì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ó jíǹde! Kò sí níhìnín yìí mọ́, Ẹ wo ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.

7 Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Pétérù wí pé, ‘Òun ti ń lọ ṣíwájú yín sí Gálílì. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’ ”

8 Wọ́n sá jáde lọ kánkán, wọn sì sáré kúrò ní ibi ibojì náà, nítorí tí wọ́n wárìrì; ẹ̀rù sì bà wọn gidigidi; wọn kò wí ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù bá wọ́n.

9 Nìgbà tí Jésù jíǹde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sè, ó kọ́ fi ara hàn fun Màríà Magidalénì, ni ara ẹni tí ó ti lé ẹ̀mi Èsù méje jáde.

10 Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún.

11 Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ti di alààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.

12 Lẹ́yìn èyí, ó sì fi ara hàn fún àwọn méjì ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà, tí wọ́n sì ń lọ sí ìgbéríko.

13 Nígbà tí wọ́n sì mọ ẹni tí i ṣe, wọ́n sì lọ ròyìn fún àwọn ìyókù, ṣíbẹ̀, àwọn ìyókù kò gbà wọ́n gbọ́.

14 Lẹ́yìn náà, Jésù fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn mọ́kànlá níbi tí wọ́n ti jìjọ ń jẹun; Ó sì bá wọn wí fún àìgbàgbọ́ àti ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba ẹ̀rí àwọn tí ó ti rí i lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ gbọ́.

15 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì máa wàásù ìyìn rere mi fún gbogbo ẹ̀dá.

16 Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí a sì tẹ̀bọmi yóò là. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò gbàgbọ́ yóò jẹ̀bi.

17 Àmì wọ̀nyí yóò sì máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ. Ní orúkọ mi ni wọ́n yóò máa lé ẹ̀mí èsù jáde. Wọn yóò máa fi èdè titun sọ̀rọ̀.

18 Wọn yóò sì gbé ejò lọ́wọ́, bí wọ́n bá sì jẹ májèlé kò ní pa wọ́n lára rárá. Wọ́n yóò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóò sì dá.”

19 Nígbà tí Jésù Olúwa sì ti bá wọn sọ̀rọ̀ báyìí tan, á gbé e lọ sí ọ̀run, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.

20 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì jáde lọ. Wọ́n ń wàásù káàkiri. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, ó sì ń fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípa àwọn àmì tí ó tẹ̀lé e.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16