Máàkù 6 BMY

Wòlíì Tí Kò Ní Ọlá

1 Jésù fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

2 Nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí sínágọ́gù láti kọ́ àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà àwọn ènìyàn púpọ̀ tí ó gbọ́, wọ́n wí pé,“Níbo ni ọkùnrin yìí gbé ti rí nǹkan wọ̀nyí? Irú ọgbọ́n kí ni èyí tí a fi fún un, ti irú iṣẹ́ ìyanu báyìí ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe?

3 À bí kì í ṣe kápẹ́ríta ni? Àbí kì í ṣe ọmọ. Màríà àti arákùnrin Jákọ́bù àti Jósẹ́fù, Júdásì àti Símónì? Àbí kì í ṣe ẹni ti àwọn arábìnrin rẹ̀ ń gbé àárin wa níhìn ín?” Wọ́n sì kọsẹ̀ lára rẹ̀.

4 Nígbà náà, Jésù wí fún wọn pé, “A máa ń bu ọlá fún wòlíì níbi gbogbo àfi ní ìlú ara rẹ̀ àti láàrin àwọn ìdílé àti àwọn ẹbí òun pàápàá.”

5 Nítorí àìgbàgbọ́ wọn, òun kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá láàrin wọn, àfi àwọn aláìsàn díẹ̀ tí ó gbé ọwọ́ lé lórí, tí wọ́n sì rí ìwòsàn.

Jésù Rán Ọmọ-ẹ̀yìn Méjìlá Jáde

6 Ẹnu si yà á nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, Jésù lọ sí àárin àwọn ìletò kéékèèkéé, ó sì ń kọ́ wọn.

7 Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì-méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́.

8 Òun sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtilẹ̀ wọn. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò, tàbí owó lọ́wọ́.

9 Wọn kò tilẹ̀ gbodọ̀ mú ìpàrọ̀ bàtà tàbí aṣọ lọ́wọ́.

10 Jésù wí pé, “Ẹ dúró sí ilé kan ní ìletò kan. Ẹ má ṣe ṣípò padà láti ilé dé ilé, nígbà tí ẹ bá wà ní ìlú náà.

11 Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn-eruku ẹṣẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn.”

12 Wọ́n jáde lọ láti wàásù ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn.

13 Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá.

A bẹ́ Jòhánù onítẹ̀bọmi lórí

14 Láìpẹ́, ọba Hẹ́rọ́dù gbọ́ nípa Jésù, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ọba náà rò pé, “Jòhánù Onítẹ́bọ́mì jínde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ”

15 Àwọn mìíràn wí pé, “Èlíjà ní.”Àwọn mìíràn wí pé, “Wòlíì bí ọ̀kan lára àwọn àtijọ́ tó ti kú ló tún padà sáyé.”

16 Ṣùgbọ́n nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́ èyí, ó wí pé “Jòhánù tí mo tí bẹ́ lórí ni ó ti jíǹde kúrò nínú òkú.”

17 Hẹ́rọ́dù tikararẹ́ sá ti ránṣẹ mú Johanu, tìkaararẹ̀ sínu túbú nítorí Hẹrodíà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀ nítorí tí ó fi ṣe aya.

18 Nítorí tí ó tẹnumọ́ ọn wí pé, “Kò tọ́ sí ọ láti fi ìyàwó arákùnrin rẹ ṣe aya.”

19 Nítorí náà ni Hẹ́rọ́díà ṣe ní ìn sínú, òun sì fẹ́ pa á, ṣùgbọ́n kò le se é.

20 Nítorí Hẹ́rọ́dù bẹ́rù Jòhánù, ó sì mọ̀ ọ́n ni olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni mímọ́, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́rọ̀ Jóhànù, ó ṣe ohun púpọ̀, ó sì fi olórí ní Gálílì.

21 Níkẹ̀yìn Hẹ́rọ́díà rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù, òun sì pèṣè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn jàǹkànjànkàn ní Gálílì.

22 Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Hẹ́rọ́díà wọlé tí ó jó. Inú Hẹ́rọ́dù àti àwọn àlèjò rẹ̀ dùn tóbẹ́ẹ̀ tí ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé,“Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ.”

23 Ó sì búra fún un wí pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́, ìbá à ṣe ìdajì ìjọba mi ni, èmi yóò fi fún ọ.”

24 Ó jáde lọ sọ fún ìyá rẹ̀ pé “Kí ní kí ń béèrè?”Ó dáhùn pé, “Orí Jòhánù Onítẹ̀bọmi.”

25 Ọmọbìnrin yìí sáré padà wá sọ́dọ̀ Hẹ̀rọ́dù ọba. Ó sì wí fún un pé, “Mo ń fẹ́ orí Jòhánù Onítẹ̀bọmi nísinsin-yìí nínú àwopọ̀kọ́.”

26 Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ, àti nítorí tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un.

27 Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀sọ ọ̀kan ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Jòhánù wá. Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Jòhánù lórí nínú túbú.

28 Ó sì gbé orí Jòhánù sí wa nínú àwopọ̀kọ́. Ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà. Òun sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ.

29 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì lọ tẹ́ ẹ sínú ibojì.

Jésù Bọ́ Ẹgbẹ̀rún Márùn-ún Ènìyàn

30 Àwọn àpósítélì ko ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni.

31 Nígbà tí Jésù rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ ti wọ́n sì ń bọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó si wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi.”

32 Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́.

33 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ni o rí wọn nígbà tí wọ́n ń lọ. Àwọn wọ̀nyí sì tí ó wá láti ìlú ńlá gbogbo sáré gba etí òkun, wọ́n sì ṣe déédé wọ́n bí wọ́n ti gúnlẹ̀ ní èbúté.

34 Bí Jésù ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀.

35 Nígbà tí ọjọ́ sì ti bu lọ tán, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ ọ́ wa, wọ́n wí fún un pé, ibi aṣálẹ̀ ni ìbí yìí, ọjọ́ sì bù lọ tán.

36 “Rán àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti lọ sí àwọn abúlé àti ìlú láti ra oúnjẹ fún ara wọn.”

37 Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, “Eyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ lébìrà osù mẹ́jọ, Ṣe kí a lọ fi èyí ra búrẹ́dì fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ.”

38 Jésù tún béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ni lọ́wọ́? Ẹ lọ wò ó.”Wọ́n padà wá jíṣẹ́ pé, “Ìṣù àkàrà márùn ún àti ẹja méjì.”

39 Nígbà náà ni Jésù sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹẹgbẹ́ lórí koríko.

40 Lẹ́sẹ̀kan-náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ní àádọ́ta tàbí ọgọgọọ́rùn-ún.

41 Nígbà tí ó sì mú ìsù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run. Ó dúpẹ́ fún oúnjẹ náà, ó bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé e kalẹ̀ ṣíwájú àwọn ènìyàn náà àti àwọn ẹja méjì náà ni ó pín fún gbogbo wọn.

42 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó.

43 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì kó agbọ̀n méjìlá tí ó kún fún àjẹkù àkàrà àti ti ẹja pẹ̀lú.

44 Àwọn tí ó sì jẹ́ àkàrà náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5000) ọkùnrin.

Jésù Rìn Lórí Omi

45 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti padà sínú ọkọ̀ kí wọn sì ṣáájú rékọjá sí Bẹtisáídà. Níbẹ̀ ni òun yóò ti wà pẹ̀lú wọn láìpẹ́. Nítorí òun fúnra a rẹ̀ yóò dúró sẹ́yìn láti rí i pé àwọn ènìyàn túká lọ ilé wọn.

46 Lẹ́yìn náà, ó lọ sórí òkè láti lọ gbàdúrà.

47 Nígbà tí ó dalẹ́, ọkọ̀ wà láàrin òkun, òun nìkan sì wà lórí ilẹ̀.

48 Ó rí i wí pé àwọ́n ọmọ-ẹyin wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá,

49 ṣùgbọ́n nígbà tí wọn rí i tí ó ń rìn, wọ́n rò pé ìwin ni. Wọ́n sì kígbe sókè lohún rara,

50 nítorí gbogbo wọn ni ó rí i, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.Ṣùgbọ́n òun sọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Ẹ mú ọkàn le! Emi ni. Ẹ má bẹ̀rù.”

51 Nígbà náà ni ó gòkè sínú ọkọ̀ pẹ̀lú wọn, ìjì líle náà sì dáwọ́ dúró. Ẹ̀rù sì bà wọ́n rékọjá gidigidi nínú ara wọn, ẹnú sì yà wọ́n.

52 Wọn kò sá à ronú iṣẹ́ ìyanu ti ìṣù àkàrà, nítorí ti ọkàn wọn yigbì.

53 Lẹ́yìn tí wọ́n la òkun náà kọjá, wọ́n gúnlẹ̀ sí Génésárétì. Wọ́n sì so ọkọ̀ sí èbúté.

54 Wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀. Àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ rí Jésù, wọ́n sì dá a mọ̀ ọ́n.

55 Wéré, wọ́n ròyìn dídé rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn sáré gbé gbogbo àwọn aláìsàn wá pàdé rẹ̀.

56 Ní ibi gbogbo tí ó sì dé, yálà ní abúlé, ìlú ńlá tàbí àrọ́ko, ńṣe ni wọ́n ń kó àwọn aláìsàn pàdé rẹ̀ ní àárin ọjà. Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí wọn fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ kàn án ni a mú láradá.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16