1 Bí wọ́n ti súnmọ́ Bẹ́tífágè àti Bẹ́tanì ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerúsálémù, wọ́n dé orí òkè ólífì. Jésù rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ṣíwájú.
2 Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn-ún nì. Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá síhìn-ín.
3 Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń se èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ”
4 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn. Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó dúró ní ìta gbangba tí a so mọ́lẹ̀.
5 Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Kí ni ẹ̀ ń ṣe, È ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?”
6 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì wọ̀nyí sọ ohun tí Jésù ní kí wọ́n sọ. Nítorí náà àwọn ènìyàn náà yọ̀ǹda fún wọn láti mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lọ.
7 Wọ́n mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jésù wá. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì bọ́ ẹ̀wù wọn, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún Jésù láti jókòó lórí rẹ̀.
8 Nígbà náà, púpọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ́ àṣọ wọn sójú-ọ̀nà níwájú u rẹ̀. Àwọn mìíràn ju ewéko ìgbẹ́ sílẹ̀.
9 Jésù wà láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn níwájú, lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé,“Hòsánà!”“Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!”
10 “Olubùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dáfídì, baba wa!”“Hòsánà lókè ọ̀run!”
11 Jésù wọ Jerúsálémù ó sì lọ sí inú tẹ́ḿpílì. Ó wo ohun gbogbo yíká fínnífínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti sú. Ó padà lọ sí Bẹ́tanì pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.
12 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Bẹ́tanì, ebi ń pa Jésù.
13 Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán ti ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so.
14 Lẹ́yìn náà, Jésù pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀.
15 Nígbà ti wọ́n padà sí Jerúsálémù, ó wọ inú tẹ́ḿpílì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹ́ḿpílì ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀.
16 Kò sì gba ẹnikẹ́ni láàyè láti gbé ẹrù ọjà títa wọlé.
17 Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣe a kò ti kọ ọ́ pé:“ ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi,ní gbogbo òrilẹ̀ èdè’?Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.”
18 Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná-ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.
19 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerúsálémù.
20 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jésù fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò-tigbòǹgbò.
21 Pétérù rántí pé Jésù ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jésù pé, “Rábì, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”
22 Jésù sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,
23 Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣí ìdí, gbé ara rẹ sọ sínú òkun’ ti kò sí ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n ti ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.
24 Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ ti yín.
25 nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì ẹni tí ó ṣẹ̀ yín. Baba yín lọ́run yóò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín.”
26 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dáríjì, Baba yín ti ń bẹ ni ọ̀run kí yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín
27 Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerúsálémù.Bí Jésù ti ń rìn kíri ni tẹ́ḿpílì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn tí ń kọ́ni ni òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀.
28 Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Àṣẹ wo ni ó fi ń se nǹkan yìí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyìí?”
29 Jésù dá wọn lóhùn pé, “Èmi yóò sọ fún un yín bí ẹ bá lè dáhùn ìbéèrè mi yìí.”
30 Ìtẹ̀bọmi Jòhánù láti ọ̀run wa ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn? “Ẹ dá mi lóhùn!”
31 Wọ́n bá ara wọn jíjòrò pé: “Bí a bá wí pé Ọlọ́run ni ó rán an wá nígbà náà yóò wí pé, ‘nígbà tí ẹ mọ̀ bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ẹ kò fi gbà à gbọ?’
32 Ṣùgbọ́n bí a bá sọ wí pé Ọlọ́run kọ́ ló rán an, nígbà náà àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rẹ̀ rògbòdìyàn. Nítorí pé gbogbo ènìyàn ló gbàgbọ́ pé wòlíì gidi ni Jòhánù.”
33 Nítorí náà, Wọ́n kọjú sí Jésù wọn sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”Nígbà náà ni Jésù wí pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò lè dáhùn ìbéèrè mi, Èmi náà kì yóò sọ fún yín àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”