1 Ní ọjọ́ kan, àwọn Farisí olùkọ́ àti àwọn òfin tí ó wá láti Jerúsálémù péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,
2 Wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́.
3 (Àwọn Farisí, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kií jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọdọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́.
4 Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bomi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bá, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)
5 Nítorí èyí àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èése tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn àṣà wa àtijọ́ nítorí wọ́n jẹun láì kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ wọn.”
6 Jésù dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òótọ́ ni wòlíì Àìṣáyà ń sọ nígbà tí ó ń ṣe àpèjúwe yín, tó wí pé:“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún miṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.
7 Ìsìn wọn jẹ́ lásán,ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkì dá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’
8 Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apákan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àà àwọn ènìyàn.”
9 Ó si wí fún wọn: “Ẹyin sáà mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ.
10 Mósè fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni?’
11 Ṣùgbọ́n ẹyin wá yí i po pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kó bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí a sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi èyí tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run.
12 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí iyá rẹ̀ mọ́.
13 Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti yín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.”
14 Lẹ́yìn náà, Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín.
15 Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́.
16 Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”
17 Nígbà tí Jésù sì wọ inú ilé kan lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tẹ̀lé é, wọ́n sì béèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó pa.
18 Jésù béèrè wí pé, “Àbí kò sí èyí tí ó yé yín nínú ọ̀rọ̀ náà? Ẹ̀yin kò rí i wí pé ohunkóhun tí ó wọ inú ènìyàn láti òde kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́?
19 Ìdí ni wí pé, Ohunkóhun tí ó bá wọ inú láti ìta, kò wọ inú ọkàn rárá, ṣùgbọ́n ó kọjá sí ikùn.” (Nípa sísọ èyí, Jésù fi hàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”)
20 Nígbà náà, ó fi kún un pé: “Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọni di aláìmọ́.
21 Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà,
22 ọ̀kánjúwà, odì-yíyàn, ìtànjẹ, ìmọ-tara ẹni, ìlara, ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀.
23 Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”
24 Nígbà náà ni Jésù kúrò ní Gálílì, ó sí lọ sí agbégbé Tírè àti Sídónì, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri.
25 Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jésù, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ Jésù.
26 Gíríkì ní obìnrin náà, Ṣíríàfonísíà ní orílẹ̀ èdè rẹ̀. Ó bẹ Jésù kí ó bá òun lé ẹ̀mí Èsù náà jáde lára ọmọbìnrin òun.
27 Jésù sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”
28 Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábílì.”
29 “Ó sì wi fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”
30 Nígbà tí ó náà padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.
31 Nígbà náà ni Jésù fi agbégbé Tírè àti Ṣídónì sílẹ̀, ó wá si òkun Gálílì láàrin agbègbè Dékápólì.
32 Níbẹ̀ ọkùnrin kan tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, àwọn ènìyàn sì bẹ Jésù pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e.
33 Jésù sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ sọ́wọ́. Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀.
34 Nígbà náà ni Jésù wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Éfátà,” èyí ni, “Ìwọ ṣí.”
35 Bí Jésù ti pàṣẹ yìí tan, ọkùnrin náà sì gbọ́ràn dáadáa. Ó sì sọ̀rọ̀ ketekete.
36 Jésù pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó.
37 Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, “Ó se ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́ràn, odi sì sọ̀rọ̀.”