Máàkù 3 BMY

1 Nígbà tí Jésù wá sí sínágọ́gù. Sì kíyèsí i ọkùnrin kan wà níbẹ̀, tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ.

2 Àwọ́n kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jésù, ítorí náà, wọn ń sọ Ọ́ bí yóò u un láradá ní ọjọ́ ìsinmi.

3 Jésù wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.”

4 Nígbà náà ni Jésù bèèrè lọ́wọ́ wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.

5 Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá.

6 Lójúkan-náà, àwọn Farisí jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ ẹ̀yin Hẹ́rọ́dù gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jésù.

Ọ̀pọ̀ Ènìyàn Tẹ̀lé Jésù

7 Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Gálílì àti Jùdíà sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

8 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrpyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Jùdíà, Jerúsálémù àti Ìdúmíà, àti láti apákejì odò Jọ́dání àti láti ihà Tírè àti Ṣídónì.

9 Nítorí ẹ̀rọ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ lati sètò ọkọ̀ ojú omi kekere kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn ẹ̀rọ̀ sẹ́yìn.

10 Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá lọ́jọ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló yí i ká, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti fi ọwọ́ kàn án.

11 Ìgbàkúùgbà tí àwọn tí ó kún fún ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú gán-án ní rẹ̀, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn-rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”

12 Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí wọn má ṣe fi òun hàn.

Jésù Yan àwọn Àpótélì Méjìlá

13 Jésù gun orí òkè lọ ó gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.

14 Ó yan àwọn méjìlá-ó pè wọ́n ní apostẹli-kí wọ́n kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí wọn kí ó lè lọ láti wàásù

15 àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èsù jáde.

16 Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn, Ṣímóní (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Pétérù)

17 Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jésù sọ àpèlé wọ́n ní Bóánájì, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).

18 Àti Ańdérù, Fílípì, Bátólómíù, Mátíù, Tómásì, Jákọ́bù (ọmọ Álíféù), Tádéù, Símónì (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó fẹ́ ará Kénánì tí ó fi ìjàngbọ̀n dojú ìjọba Rómù bolẹ̀)

19 Àti Júdásì Ísíkáríọ́tù, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.

Jésù àti Bélísébúbù

20 Nígbà náà ni Jésù sì wọ inú ilé kan, àwọn ẹ̀rọ̀sì tún kórájọ, tó bẹ́ẹ̀ tí Òun àti àwọn Ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ kò rí ààyè láti jẹun.

21 Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wá láti mu un lọ ilé, nítorí tí wọn wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”

22 Àwọn olùkọ́ni-ni-òfin ṣọkàlẹ̀ wá láti Jérúsálẹ́mù, wọn sì wí pé, “Ó ni Béélísébúbù, olórí àwọn ẹ̀mí Èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”

23 Jésù pè wọ́n, ó sì fi òwé bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èsù ṣe lè lé èsù jáde?

24 Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀.

25 Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò leè dúró.

26 Bí Èṣù bá sì díde sí ara rẹ, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé.

27 Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní erù lọ, bí kò se pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀.

28 Lóòótọ́ ní mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a ó dárí jin àwọn ọmọ ènìyàn, àti gbogbo ọ̀rọ̀ òdì.

29 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú èwù ẹ̀bi àìnípẹ̀kun.”

30 Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, “Nípa agbára ẹ̀mí Èṣù ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.”

Ìyá àti àwọn Arákùnrin Jésù

31 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dé. Wọ́n dúró lóde, wọ́n sì rán ẹnìkan sí i pé kí ó pè é wá.

32 Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde.”

33 Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, “Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi?”

34 Ó sì wò gbogbo àwọn tí ó jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ yíká, ó sì wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi:

35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16