23 Ní àsìkò náà gan-an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú sínágọ́gù wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé,
24 “Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jésù ti Násárẹ́tì? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!”
25 Jésù si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúro lára rẹ̀.”
26 Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e sánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà.
27 Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrin ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ titun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.”
28 Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbégbé Gálílì.
29 Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú sínágọ́gù, wọ́n lọ pẹ̀lú Jákọ́bù àti Jòhánù sí ilé Símónì àti Ańdérù.