3 “Ohùn ẹnìkan tí ń kígbe ní ihà,‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,ẹ se ojú-ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”
4 Jòhánù dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní ihà, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
5 Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Jùdíà, àti gbogbo ènìyàn Jerúsálémù jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọmi ni odò Jọ́dánì, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
6 Jòhánù sì wọ ẹ̀wù tí a fi irun ràkúnmí hun. Ó sì lo ìgbànú awọ. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.
7 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹṣẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú.
8 Èmi ń fi omi se ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ se ìtẹ̀bọmi yín.”
9 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jésù ti Násárẹ́tì ti Gálílì jáde wá, a sì ti ọwọ́ Jòhánù tẹ̀ Ẹ bọmi ní odò Jọ́dánì.