30 Ìyá ìyàwó Símónì tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jésù nípa rẹ̀.
31 Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójú kan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
32 Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí òòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá.
33 Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà.
34 Jésù sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú aláìsàn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í se.
35 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jésù nìkan jáde lọ sí ihà kan, láti lọ gbàdúrà.
36 Símónì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a.