35 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jésù nìkan jáde lọ sí ihà kan, láti lọ gbàdúrà.
36 Símónì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a.
37 nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”
38 Jésù sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.”
39 Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbégbé Gálílì, ó ń wàásù nínú àwọn sínágọ́gù. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.
40 Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradà. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.”
41 Jésù kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.”