41 Jésù kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.”
42 Lójúkan-náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.
43 Jésù sì kìlọ̀ fún un gidigidi
44 Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mósè pa láṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a múláradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.”
45 Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkì, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jésù kò sì le wọ ìlú ní gba-n-gba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní ihà. Ṣíbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.