6 Jòhánù sì wọ ẹ̀wù tí a fi irun ràkúnmí hun. Ó sì lo ìgbànú awọ. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.
7 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹṣẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú.
8 Èmi ń fi omi se ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ se ìtẹ̀bọmi yín.”
9 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jésù ti Násárẹ́tì ti Gálílì jáde wá, a sì ti ọwọ́ Jòhánù tẹ̀ Ẹ bọmi ní odò Jọ́dánì.
10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó sí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọkalẹ̀ lé E lórí.
11 Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ìwọ ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
12 Lẹ́sẹ̀kan-náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jésù sí ihà,