1 Nígbà náà, Jésù kúrò ní Kapanámù. Ó gba gúsù wá sí agbègbè Jùdíà, títí dé ìlà oòrùn odò Jọ́dánì. Bí i ti àtẹ̀yìnwá, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kọ́ wọn pẹ̀lú bí i ìṣe rẹ̀.
2 Àwọn Farisí kan tọ̀ ọ́ wá, láti dán an wò. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó ha tọ̀nà fún ènìyàn láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?”
3 Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni Mósè pa láṣẹ fún un yín nípa ìkọ̀sílẹ̀.”
4 Wọ́n dáhùn pé, “Mósè yọ̀ǹda ìkọ̀sílẹ̀. Ohun tí ọkùnrin náà yóò ṣe ni kí ó fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, lẹ́yìn èyí, ààyè wà láti kọ obìnrin náà sílẹ̀.”