13 Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tọ Jésù wá kí ó lè súre fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kígbe mọ́ àwọn tí ń gbé àwọn ọmọdé wọ̀nyí bọ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ yọ Jésù lẹ́nu rárá.
14 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé kékeré wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun nítorí pé irú wọ́n ni ìjọba Ọlọ́run.
15 Mo ń sọ òótọ́ fún un yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti mọ̀, pé, ẹni tí kò bá wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bi ọmọ kékeré, a kì yóò fún un láàyè láti wọ ìjọba rẹ̀.”
16 Nígbà náà, Jésù gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn. Ó sì súre fún wọn.
17 Bí Jésù ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò kan, ọkùnrin kan sáré wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kúnlẹ̀, ó béèrè pé, “Olùkọ́ rere, kí ni èmi yóò ṣe láti jogún ìyè àìnipẹ̀kun?”
18 Jésù béèrè pé, Arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere.
19 Ìwọ mọ àwọn òfin bí i: Má ṣe pànìyàn, má ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe purọ́, má ṣe rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.”