29 Jésù dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ohúnkóhun sílẹ̀ bí: ilé, tàbí àwọn arákùnrin, tàbí àwọn arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí baba, tàbí àwọn ọmọ tàbí ohun ìní,
30 tí a kì yóò fún padá ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí àti ilẹ̀, tàbí bí inúnibini tilẹ̀ wà. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun.
31 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó sì kẹ́yìn yóò síwájú.”
32 Nísinsìn yìí, wọ́n wà lójú ọ̀nà sí Jerúsálémù. Jésù sì ń lọ níwájú wọn, bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti ń tẹ̀lé e, ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn. Ó sì tún mú àwọn méjìlá sí apá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun gbogbo tí a ó ṣe sí i fún wọn.
33 Ó sọ fún wọn pé, “Awa ń gòkè lọ Jerúsálémù, a ó sì fi Ọmọ-Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ òfin lọ́wọ́. Wọn ni yóò dá lẹ́bi ikú. Wọn yóò sì fà á lé ọwọ́ àwọn aláìkọlà.
34 Wọn yóò fi se ẹlẹ́yà, wọn yóò tutọ́ sí ní ara, wọn yóò nà pẹ̀lú pàsán wọn. Wọn yóò sì pa, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò tún jíǹde.”
35 Lẹ́yìn èyí, Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè wá sọ́dọ̀ Jésù. Wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, wọ́n wí pé, “Olùkọ́, inú wa yóò dùn bí ìwọ bá lè ṣe ojú rere ohunkóhun tí a bá béèrè fún wa.”