3 Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni Mósè pa láṣẹ fún un yín nípa ìkọ̀sílẹ̀.”
4 Wọ́n dáhùn pé, “Mósè yọ̀ǹda ìkọ̀sílẹ̀. Ohun tí ọkùnrin náà yóò ṣe ni kí ó fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, lẹ́yìn èyí, ààyè wà láti kọ obìnrin náà sílẹ̀.”
5 Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn, ó sì wí pé, “Mósè kọ òfin yìí fun un yín nítorí ẹ jẹ́ ọlọ́kàn líle.
6 Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo.
7 Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì faramọ́ aya rẹ̀.
8 Òun àti ìyàwó rẹ̀ yóò di ara kan náà. Nítorí náà, wọn kì í tún ṣe méjì mọ́ bí kò ṣe ẹyọ ọ̀kan ṣoṣo.
9 Nítorí náà ohun ti Ọlọ́run bá sọ dọ̀kan, ki ẹnikẹ́ni máa ṣe yà wọ̀n.”