31 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó sì kẹ́yìn yóò síwájú.”
32 Nísinsìn yìí, wọ́n wà lójú ọ̀nà sí Jerúsálémù. Jésù sì ń lọ níwájú wọn, bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti ń tẹ̀lé e, ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn. Ó sì tún mú àwọn méjìlá sí apá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun gbogbo tí a ó ṣe sí i fún wọn.
33 Ó sọ fún wọn pé, “Awa ń gòkè lọ Jerúsálémù, a ó sì fi Ọmọ-Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ òfin lọ́wọ́. Wọn ni yóò dá lẹ́bi ikú. Wọn yóò sì fà á lé ọwọ́ àwọn aláìkọlà.
34 Wọn yóò fi se ẹlẹ́yà, wọn yóò tutọ́ sí ní ara, wọn yóò nà pẹ̀lú pàsán wọn. Wọn yóò sì pa, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò tún jíǹde.”
35 Lẹ́yìn èyí, Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè wá sọ́dọ̀ Jésù. Wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, wọ́n wí pé, “Olùkọ́, inú wa yóò dùn bí ìwọ bá lè ṣe ojú rere ohunkóhun tí a bá béèrè fún wa.”
36 Jésù béèrè pé, “Kí ni Ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi ó ṣe fún un yín?”
37 Wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé, “Jẹ́ kí ọ̀kan nínú wa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ẹnikejì ní ọwọ́ òsì nínú ògo rẹ!”