45 Nítorí, Èmi, Ọmọ ènìyàn kò wá sí ayé kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún mi, ṣùgbọ́n láti lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, àti láti kú fún ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”
46 Wọ́n dé Jẹ́ríkò, bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jẹ́ríkò, ọkùnrin afọ́jú kan, Bátíméù, ọmọ Tíméù jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń sagbe.
47 Nígbà tí Bátiméù gbọ́ pé Jésù ti Násárẹ́tì wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, “Jésù ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi.”
48 Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́.” Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, “Jésù ọmọ Dáfídì ṣàánú fún mi.”
49 Nígbà tí Jésù gbọ́ igbe rẹ̀, ó dẹṣẹ̀ dúró lójú-ọ̀nà, ó sì wí pé, “Ẹ pè é kí ó wá sọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n wí pé, “Tújúká!, dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ! Ó ń pè ọ́.”
50 Lẹ́sẹ̀kan-náà, Bátíméù bọ́ aṣọ rẹ̀ sọnù, ó fò sókè, ó sì wá sọ́dọ̀ Jésù.
51 Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ?”Afọ́jú náà dáhùn pé, “Rábì, jẹ́ kí èmi ki o ríran.”