6 Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo.
7 Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì faramọ́ aya rẹ̀.
8 Òun àti ìyàwó rẹ̀ yóò di ara kan náà. Nítorí náà, wọn kì í tún ṣe méjì mọ́ bí kò ṣe ẹyọ ọ̀kan ṣoṣo.
9 Nítorí náà ohun ti Ọlọ́run bá sọ dọ̀kan, ki ẹnikẹ́ni máa ṣe yà wọ̀n.”
10 Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù nìkan wà nínú ilé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun kan náà.
11 Jésù túbọ̀ ṣe àlàyé fún wọn pé, “Nígbà tí ọkùnrin kan bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí ó bá sì fẹ ẹlòmíràn, irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà sí obìnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé níyàwó.
12 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí obìnrin kan bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì fẹ́ ọkùnrin mìíràn, irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà.”