1 Bí wọ́n ti súnmọ́ Bẹ́tífágè àti Bẹ́tanì ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerúsálémù, wọ́n dé orí òkè ólífì. Jésù rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ṣíwájú.
2 Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn-ún nì. Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá síhìn-ín.
3 Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń se èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ”
4 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn. Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó dúró ní ìta gbangba tí a so mọ́lẹ̀.
5 Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Kí ni ẹ̀ ń ṣe, È ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?”
6 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì wọ̀nyí sọ ohun tí Jésù ní kí wọ́n sọ. Nítorí náà àwọn ènìyàn náà yọ̀ǹda fún wọn láti mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lọ.
7 Wọ́n mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jésù wá. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì bọ́ ẹ̀wù wọn, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún Jésù láti jókòó lórí rẹ̀.