12 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Bẹ́tanì, ebi ń pa Jésù.
13 Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán ti ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so.
14 Lẹ́yìn náà, Jésù pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀.
15 Nígbà ti wọ́n padà sí Jerúsálémù, ó wọ inú tẹ́ḿpílì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹ́ḿpílì ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀.
16 Kò sì gba ẹnikẹ́ni láàyè láti gbé ẹrù ọjà títa wọlé.
17 Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣe a kò ti kọ ọ́ pé:“ ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi,ní gbogbo òrilẹ̀ èdè’?Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.”
18 Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná-ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.