22 Jésù sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,
23 Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣí ìdí, gbé ara rẹ sọ sínú òkun’ ti kò sí ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n ti ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.
24 Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ ti yín.
25 nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì ẹni tí ó ṣẹ̀ yín. Baba yín lọ́run yóò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín.”
26 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dáríjì, Baba yín ti ń bẹ ni ọ̀run kí yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín
27 Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerúsálémù.Bí Jésù ti ń rìn kíri ni tẹ́ḿpílì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn tí ń kọ́ni ni òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀.
28 Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Àṣẹ wo ni ó fi ń se nǹkan yìí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyìí?”