Máàkù 12:14-20 BMY

14 Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ tìrẹ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Késárì?

15 Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un?” Ṣùgbọ́n Jésù mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.”

16 Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?”Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Késárì ni.”

17 Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Késárì fún Késárì. Ṣùgbọn ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀.

18 Àwọn Ṣadusí tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé,

19 “Olùkọ́, Mósè fún wa ní òfin pé: Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà.

20 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú láìbímọ.