15 Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un?” Ṣùgbọ́n Jésù mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.”
16 Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?”Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Késárì ni.”
17 Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Késárì fún Késárì. Ṣùgbọn ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀.
18 Àwọn Ṣadusí tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé,
19 “Olùkọ́, Mósè fún wa ní òfin pé: Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà.
20 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú láìbímọ.
21 Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣu obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó sú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ.