17 Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Késárì fún Késárì. Ṣùgbọn ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀.
18 Àwọn Ṣadusí tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé,
19 “Olùkọ́, Mósè fún wa ní òfin pé: Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà.
20 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú láìbímọ.
21 Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣu obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó sú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ.
22 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe títí àwọn méjèèje fi kú láìbímọ. Ní òpin gbogbo rẹ̀, obìnrin tí a ń wí yìí náà kú.
23 Ohun tí a fẹ́ mọ̀ nìyì: Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àwọn arákùnrin méjèèje ló fẹ́ obìnrin náà, ìyàwó o ta ni yóò jẹ́ nínú wọn lọ́jọ́ àjíǹde?”