26 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Ẹ́kísódù, nípa Mósè àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mósè pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù.’
27 Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”
28 Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jésù ti dáhùn dáadáa. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?”
29 Jésù dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Ísírẹ́lì, Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ ọ̀kan náà, Ọlọ́run kan náà sì ni.
30 Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’
31 Èkejì ni pé: ‘Fẹ ọmọnikejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.”
32 Olùkọ́ ófin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan.