29 Jésù dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Ísírẹ́lì, Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ ọ̀kan náà, Ọlọ́run kan náà sì ni.
30 Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’
31 Èkejì ni pé: ‘Fẹ ọmọnikejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.”
32 Olùkọ́ ófin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan.
33 Àti pé, mo mọ bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti fẹ́ ẹ pẹ̀lú gbogbo agbára mi, àti pẹ̀lú pé kí n fẹ́ràn ọmọnìkéjì mi gẹ́gẹ́ bí ara mi, ju kí n rú oríṣiiríṣii ẹbọ lórí i pẹpẹ ilé ìsìn.”
34 Jésù rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jésù sọ fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jésù.
35 Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn Ọmọ-Ènìyàn nínú tẹ́ḿpílì, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “È é ṣe tí àwọn olùkọ́-òfin fi gbà wí pé Kírísítì náà ní láti jẹ́ ọmọ Dáfídì?