Máàkù 12:7-13 BMY

7 “Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọmọ baba olóko, wọ́n sọ fún ara wọn pé, ‘Ọmọ rẹ̀ ló ń bọ̀ yìí. Òun ni yóò jogún oko yìí tí baba rẹ̀ bá kú. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, lẹ́yìn náà oko náà yóò di tiwa.’

8 Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ kúrò nínú oko.

9 “Kí ni ẹ rò pé baba olóko yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣélẹ́. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀.

10 Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹṣẹ yìí nínú ìwé mímọ́:“ ‘Òkúta tí àwọn ọmọ̀lé ti kọ̀ sílẹ̀òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé.

11 Èyí ni iṣẹ́ Olúwaó sì jẹ́ ìyàlénu lójú tiwa’?”

12 Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olúkọ̀ òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà fẹ́ mú Jésù lákókò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ.

13 Ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn Farisí pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Hẹ́rọ́dù wá sọ́dọ̀ Jésù, láti fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, títí yóò fi sọ ohun kan kí wọn lè rí fi mú.